Tuesday, June 21, 2011

IMO, IGBORAN, ATI JIJE ALABUKUN – FUN.

Bi eyin ba Mo nkan wonyi, ALABUKUN – FUN ni yin, bi enyin ba n se won.

Gbolohun ti wa ni oke yii ti enu Jesu Kristi jade leyin igbati o ti ko awon omo – eyin ni sise ise isin elomiran ati iyi ti o wa leyin re ninu Johanu 13:1 -17. O je ki oye won wipe ise Pataki ati jije eni iyi duro lori iwa irele ti a ni lati le sise sin elomiran. Sugbon eko wa duro lori awon oro Pataki meta ti a ri ka ninu ese ketadinlogun. Awon oro meteta naa ni: Imo, Igboran, ati alabukun – fun.

IMO nibiyi tumo si:

  • Imo Olorun otito – Abuda Re, iwa Re, ati ife Re.
  • Imo oro Olorun ati igbekele re, Pataki julo awon ipin ti o so nipa igbala.
  • Imo nipa ara eni gege bi eniti o ti subu sinu ese ti o si nilo iranlowo lati dide (Romu 3:23).
  • Mimo Jesu Kristi gege bi Omo Olorun tooto ti a ran si ofun igbala emi re (John 3:16)

IGBORAN tumo si:

  • Bibowo fun ife Olorun ati gbogbo ofin Re.
  • Sise ife Olorun, ti ki n se ti asehan tabi nitori ere ti a o rigba nibe, sugbon lati inu emi irele ti ogbooro.
  • Titele ase Olorun, ti ki n se nitori ti o tele aigboran, sugbon lati inu okan ti o n fi emi ife han si Jesu Kristi.
  • Jije olotito titi de opin. Eyi tumo si igboran nigba gbogbo ati ni gbogbo ona.

ALABUKUN fun je ayorisi imo ati igboran. Lara re ni:

  • Ibale okan lai si rudurudu tabi iporuru okan nigba kankan. (Mattiu 11:18)
  • Alaafia lati inu ati eri okan daradara pelu Olorun ati gbogbo eniyan.
  • Wiwa laini ebi okan, irunu, ati inu buruku si enikeni. Eyi tumo si idunnu ati jije eni itewogba niwaju Olorun.
  • O tun tumo si ire, aanu, isegun, igbala, ati ireti ti ko nipekun.
  • Oore – ofe ti o to ati ibewo lati oke wa ni asiko aini (2 Korinti 12:9)

IPAARI.

Jije alabukun – fun lati odo Olorun ko ni nkan se nipa jije omo ijo tabi jije olusin ni gbogbo igba. Ko si ni nkan se pelu ohun ti eniyan je ninu ile Olorun tabi ise ti eniyan n se ninu ile Olorun. Sugbon jije alabukun – fun lati oke wa duro lori MIMO ati SISE ife ati ase Olorun. Jesu wipe Bi eyin ba MO nkan wonyi, ALABUKUN –FUN ni nyin, bi eyin ba n SE won.

Tuesday, March 29, 2011

IDENA SI KIKO IJO TI O NI IFE (APA KEJI)

1. OJUSAAJU.
Ojuse ijo ni lati setoju awon elomiran. Nitooto, ise itoju ni koko ise ise-iranse. Bi ijo ba je eyi ti n setoju awon eniyan re, awon ti nje anfaani itoju naa yoo fe lati mo Olorun ti se olutoju eni. Bi gbogbo aye ti gba Olorun ni baba duro gege bi ipile ti o se Pataki julo ni eko imo Olorun nipa ise-iranse itoju. Isepataki eyi ni pe gbogboeda je ti Olorun. Fun idi eyi, gege bi asoju Olorun, ijo ni ojuse si awon eniyan ati si awujo.
Ni opolopo igba, awon eniyan ti won wa sinu ijo ni awon aini lorisirisi. Ijo yoo ma ja Olorun kule bi o b di oju si re awon aini yii. Poolu Aposteli fi oro wonyi gba awon ti owa ni ijo Galatia nimoran. “nje bi a ti n ri akoko, e je ki a maa soore fun gbogbo eniyan ati paapaa fun awon ti se ara ile Igbagbo” (Galatia 6:10). Ni sise eyi, poolu kilo pe, “ mo pase fun o niwaju Olorun ati Kristi Jesu ati awon angeli ayanfe, ki iwo ki o maa se akiyesi awon nkan wonyi, lai se ojusaaju, lai fi egbe se Ohunkohun (Timotiu kinni 5:21).
Olorun seun fu awon Aposteli igbaani. Isele ti o se ninu ise awon Aposteli le safihan ijo gege bieyi ti asa re ko han si enikeni, alainifee ati eyi ti o kun fun ojusaaju; Sugbon oro ko ri bee. A yan awon daikoni, aisegbe si bori. A ko le so pe ijo ti won ti yan awon kan ni iposi, ti ojusaju ati isegbe si ti gbale kan, je ijo ti o ni ife, eyi yoo si di won lowo lati mu ife Olorun to awon ti won wa ni ayika won lo.
Ninu ijo ti ife wa, a ko gbodo fi aidogba pin awon ohun ti ati seto fun itoju awon eniyan. A gbodo wa ona lati mu ki osuwon wa je ti ori-o-jori. Ni opolopo igba, Nigba ti awon eniyan ba so pe awon yanju or okan ni ibamu pelu amuye re; nse ni won fi aaye sile fun ojusaaju lati bori. Nigbati eyi ba sele, die ninu awon ti won wa ninu ijo yoo rii gege bi ami isota ati ikosile. Eyi yoo mu idibaje ba afefe ife ti o ti n fe ninu ijo naa tele ri, yoo si tun di itesiwaju emi ife alajopin lowo. Labe bi ot wu ki ori, a gbodo ygo fun ojusaaju.
Oniwaasu kan so itan Okunrin kan ti olo josin ninu ijo kan ni ojo kokanlelogbon osu kejila (31st December) odun kan. O dahun si ipe Ihinrere, o jowo aye re fun Olorun, o si fi ife inu re lati darpo mo ijo naa han. O le beer wipe, bawo ni o ti pe to ki Olorun to dariji eni ti o fi otito inu re jewoawon ese re.
Okunrin naa lo fun isin ojo kinni odun titun ninu ijo naa, a fi I han, a fun ni owo idapo, a gba a lati je omo ijo naa, a si gbadura fun un. Nirole ojo kinni yii gan-an ni Okunrin naa di oloogbe awon ibeere kan je jade. Awon or okan jeyo fun ijiroro. Arin gbugbun oro naa ni wipe nje o ye ki awon se Okunrin yii gege bi omo ijo lekunrere, ki won si fun ni gbogbo eto itoju ijo? Oniwaasu naa gbagfbo pe omo ijo ni, a si gbodo fun ni eto omo ijo. Bi a ba se eleyii, ijeri ijo ninu awujo naa yoo tubo ni gbara sii. Kin ni I ba je ipo ijo agbegbe re lori oro yii?


2. ISE – IRANSE ONIWAASU.
Ipo adari se Pataki fun kiko awujo to ni ife. Bi ijo ti dagba to ninu emi ni a gbodo fi iwea oyaya, ife ati ikaanu awon omo ijo ati oniwaasu se losoo. Ninu gbogbo awon ile – eko giga ijo Onitebomi ti nkoni ni eko imo Olorun, itoju lati odo oniwaasu ati agbani ni imoran je awon eko ti o pon dandan fun gbogbo ojise Olorun. A beere pe ki oniwaasu kookan safihan iwa ife fun gbogbo awon omo ijo.
Awon oniwaasu ati awon adari io wa gbodo mo-on-mo nifee si kiko ijo ti n fanimora. Eyi bere nipa sise amudagba okan oniwaasu. Okan ni a fi n se ami ife. Awon oniwaasu gbodo ni ife tooto. Ki won si fi idunnu sise oluso-aguntan. O soro lati nifee awon ti ko rorun lati feran, awon eniyan ti won soro ati awon ti won maa n gan iran wa. Sugbon a gbodo feran won , koda nigbati a ba wa laarin rukerudo, bi o ba je looto ni a je ti Kristi.
Titele apere Jesu bere pelu okan ikaanu ti a sagbekale re nipase itetisile. Ipa ti oniwaasu ni lori awon eniyan re je eso imo ikaanu ati isetoju ti oluso-aguntan. Awon eniyan ko ni se aniyan lati mo boya o je eni ti n se itoju eni, ayafi bi o ba se aniyan lati mo won ninu-lode. Ipa ti eniyan ni lori eni maa n po sii, Sugbon ki I dede sele. Ijo kan le ma ni ife tabi ki o ni ipa lori awon eniyan ju bi ise – iranse oniwaasu re bar ti mo lo.

AWON IBEERE FU AYEWO ATI IJIRORO.
1. Kin ni awon abala miran, yato fun eto itoju, nibi ti eri ojusaasju ti han ninu awon ijo kan?
2. Bawo ni ipo ti enikan dimu se maa n ni ipa lori ibasepo re ninu ijo?
3. Jeki awonomoijo so awon nnkan to le pa Alaafia ati irepo run ninu ijo.

IDENA SI KIKO IJO TI O NI IFE

Akojopo awon onigbagbo ni ijo je. Oro ti a npe ni ekklesia toka si akojopo keekeeke ti awon onigbagbo – “ijo ti o wa ni ile won” (Romu 16:5), ati apejopo nla ti I se ti opolopo iru awon agbo bee – “ ti gbogbo ijo”(Romu 16:23). Nigba ti aba n sayewo awon onigbagbo ni orirsiris ibi, oro ti n toka si ohun ti o ju eyo kan lo ni a maa n lo (Galatia 1:2,22). A tun le pe e ni ijo agbaye.
Aniyan wa nibi yii ni pipejopo awon onigbagbo die nibi kan pato, itenumo wa ni ti ijo Onitebomi ti agbegbe. Ohun ti a o maa gbe yewo jo mo awon idena si kiko ijo Onitebomi agbegbe to ni ife.
1. EDE.
Ede ni oko si I ibanisoro. O maa n ran wa lowo lati so ero, iran ati ete eni. A tun le lo alti fi asiri pamo fun elomiran. Ohun idena akoko fun kiko ijo to ni ife ni ilo ede kan naa nibi ti a ti nilo ede meji tabi ju bee lo. A ti yee wo, a si ti fi idi re mule pe logan ti eniyan ba gbo ti enikan n so ede re ni ile ajeji, ara iru alejo bee a wale, ibanidoree yoo si bere loju ese. Ijo naa le lo iru ogbon lilo ede tabi awon ede ti yoo mu owoja iwaasu Ihinrere won kan opolopo eniyan. Nipase eyi, ijo naa yoo fa opolopo agbo ti o wa ninu awujo naa mora. Ijo ko gbodo yo Nigba ti enika ko ba ni anfaani lati iwaasu Ihinrere losoose nitori aigbo ede ti won n so. Nigba ti a ko ba mo-on-mo tirak lati ri daju pe owoja eto Ihinrere wa kan gbogbo eniyan, boya nipa lilo ede ti yoo ye gbogbo won tabi nipa lilo ogbifo, gege bi oro naa ba ti gba, eyi yoo yori si ajo awon eniyan ti won se Pataki nitori agbara, talenti ati oro won dipo awujo awon eniyan ti won gbagbo ninu eto ati anfaai kan naa fun gbogbo eniyan.
2. AWON IWA TABI ABUDA AWON ENIYAN LAPAPO.
Awon eniyan ni a npe ni ijo, ise ijo si ni lati mu Ihinrere de odo awon elomiran. Igabakuugba ti a ba si soro ijo, awon eniyan ni koko Pataki ibe. A l ri ile ti o lewa laisi awon eniyan ti won ni ife nibe. Ijo nilo awon eniyan ti won ni iwa oyaya, ti won yoo lo anfaani imoyi ewa ile Ijosin won fun Ihinrere.
Awon kan wa ti won maa n daamu Alaafia ati ife ti owa ni ijo Onitebomi agbegbe. Won ko padanu Ohunkohun ni ti won, Sugbon ohun ti ijo n padanu po pupo. Won ja Olorun kule nipa kiko lati lo fun awon eto emi ni ijo agbegbe won, nibi ti a ti le mu ki ero won wulo fun kristi. Won je asoju awon igbimo oselu laarin ijo agbegbe. Awon anfaani ati ipo ni afojusun won, ki I se awon ise ati ilosiwaju ijo. Ni akoko ipade – igbimo ijo lapapo, eyi ti oye ki a maa pe ni “wakati oko – owo Olorun”, iru awon eniyan bee ni won maa n se agbekale, ti won si maa n gbaruku ti awon ipinu ti won ti se ninu ipade to saju ipade eyi ti o maa n fi aworan ijo ti ko ni ife han fun awon omo ijo titun. A ni lati sora se.
Ko si eni ti o le yii wa tabi abuda elomiran pada. O di dandan ki eefin iru iwa tabi abuda awon eniyan bee reu tuu ninu awon ipade ijo Pataki. Jerry Akinsola sapejuwe iru awon eniyan Meje ti won wa ninu agbajo ijo ati ti awujo. Meta ninu won jo mo ori-oro awon eniyan ti won soro. Awon naa ni a soro nipa won nisale yii.
 Ajegaba.
Iru eniyan yii saba maa n ro awon elomiran, o maa n fi agbara mu won tabi ki o se inunibini si won lati mu ki won se ife re. bi a ko ba ki iru eni be wo daadaa, a o le ma jeki igbimo ronu jinle, ki won si sise daadaa. Iru eni bee ni idi ti awon iwoye tire fi dara ju ti awon miran lo. Ni sise agbekale ero re, iru eni bee je apase-waa, alainidariji ati alaikonimora. Bi iru eni bee ba n ddari ise iranse patski ninu ijo ninu ijo, o se!, nipa iwa eni naa, awon eniyan yoo ri ijo naa gege bi eyi ti ko ni ife.
 Oniroyin
Eni yii ni isoro nipa pipa oro mo. O maa n tu asiri ero ati ijiroro igbimo sita. O maa n mu ki awon eniyan ma le gba Igbimo na gbo. Bi iru awon eniyan bayii ba po ninu ijo, opolopo awon eniyan ko ni ni igbekele ninu awon omo ijo naa lapapo.
 Oluwoye – ibi.
Eni yii maa n pin eru kiri ni. Oun ni o saba maa n mo idi ti awon eniyan ko fi gbodo dagba le nkan. Bi a ko ba ki iru eni bee wo, o le ma je ki igbimo re se ohun ti oye ni sise. Iru eni bee ma n pa iran ni. Awon oludati ni iru eni bee ma n lepa, iru won kii si ni ife si ayipada. O maa n je ki ijo padanu awon ti won maa n ni ife si aipada. Ni afikun si awon nnkan ti a ko si oke yii, onkowe yii gbagbo pe a le toka si awon eniyan meji miran ti awon naa soro.
 Asoju Awon eniyan.
Eni yii maa n fi ara re han gege bi asoju awon eniyan ti ko fi oro lo ni igba kankan ri, awon eniyan ti won ko fun ni ase, ti ko si ja fun ife okan won. Ede ti o ma nlo jo eyi, “ohun ti awon eniyan so ni yii” tabi gbogbo yin ni e o gba pelu mi pe…..” Nigba miran, iru eni bee le maa soro lati inu eto ikoko kan ti o ti se.
A gbodo teti si iru eni bee, ki a esi wa fun un si da lori awon ilana, otito ati apere. Eni naa je alayiida, ti ko ni ife.
 Amoye onilana.
Eni yii ni eni ti o maa n fa ipinnu sise seyin tabi ti ki I je ki atete bere ise lori awon ipinnu ti a ti se. iru eni bee je oga ninu reran ile leti ofin kan ti won gbodo mu lo, ipinnu kan ti won se tele ri, ati bi o ti nilo ki won sora se. iru eni bee le tetet fa oluwoye-ibi wo inu egbe re. ni tire, pele ni a fi n pamukuru pele.


Awon ibeere fu ayewo ati ijiroro.
1. Je ki omo ijo kan pin nipa iru imolara ti oni Nigba ti o pade enikan ti o le so ede re ni ile ibomiran.
2. Kin ni ijo le lse lati laja laarin awon eniyan ti iwa/abuda won n kolu ara won ninu ijo? Poolu fi ilana kan lele fun wa ninu Filipi 4:1-3

Tuesday, February 15, 2011

GBIGBA AWON ENIYAN SINU IJO PELU IFE (APA KEJI)

1. EKO.

Aimokan ni oogun. Oogun re naa ni wiwa imo. Imo ni idakeji, agbara ni imo je. Ni afikun, o je ohun-elo ironi lagbara. O ye ki eni ti a gbala ti ba Olorun pade. Sugbon sa, o le ma mo nipa Olorun pupo ati bi o ti le ba a rin lons ti o lere. O nilo ki a se eto igbani-wole to fanimora fun awon omo Ijo titun.

Rick Warren fi lele wi pe, Ijo kankan ko gbodo yehun lori otito pe won nilo lati je ki omo Ijo titun la liana eto ifinimole koja ki a to gba won sinu Ijo lekunrere. O da a loju pe eyi ni idanwo akoko fun didan ifara-eni-jin omo Ijo titun si Ijo wo nipa gbigba lati gba eko fun ete ati ilana Ijo.

O damoran pe a gbodo beere pe ki omo Ijo titun naa pari kilaasi re nitori pe o je okan lara agbara Ijo ati ona lati pese awon ti yoo mu idagbasoke ba ara Kristi.

Ohun ti wa loke yii n gbiyanju lati so fun wa pe enikeni ti oba kuna lati gba eko Ijo le ma je ohun-elo rere fun mimu ara Kristi dagba. Bibeli n ko wa pe,

Gbogbo iwe Mimo ti o ni imisi Olorun ni o si ni ere fun eko, fun ibani-wi, fun itoni, fun ikoni ti owa ninu ododo. Ki eniyan Olorun ki o le pe, ti a ti mura sile patapata fun ise rere gbogbo. (Timotiu keji 3:16-17). Ni afikun, Olorun ti fi awon kan funni bi Aposteli; ati awon miran bi Wolii; ati awon miran bi efangelisti, ati awon miiran bi oluso-aguntan ati olukoni; fun asepe awon eniyan mimo fun ise-iranse, fun imudagba ara Kristi: titi gbogbo wa yoo fi de isokan Igbagbo ati imo omo Olorun, titi a o fi di Okunrin, titi a o fi de iwon gigun ekun Kristi: ki awa ki o mase je ewe mo ti a n fi gbogbo afefe eko ti siwaju ati seyin, ti a si n gba kiri, nipa itanje eniyan nipa arekereke fun ogbonkogbon ati muni sina (Efesu 4:11-14).

Fun idi eyi, a gbodo ko awon eniyan lati mo ohun t se awon ilana ati ise Ijo. Gege bi omo Ijo Onitebomi, a ni awon ogun ti wa to yato, to si niye lori. A gbodo mu ki awon omo Ijo titun mo, o kere tan, awon ipo ilana onipele-meje ti o wa nisale yii.

i. Ase Bibeli ati Jesu Kristi nikan.

ii. Iribomi awon onigbagbo nipa itebomi patapata.

iii. Ounje ale Oluwa gege bi ounje iranti ti Olorun le lo fun ete Re.

iv. Okan yiye : gbogbo awon onigbagbo ni I se alufa.

v. Iduro-sinsin ipamo awon eniyan Mimo.

vi. Ominira esin.

vii. Idaduro Ijo agbegbe.

Bi enikeni tabi Ijo kan ba kuna lati safihan awon ilana ati ise to je mo awon wonyi, lati inu itan wa ni awo omo Ijo Onitebomi ti maa n setan lati so pe “Bi ko ba gba pelu wa lori awon Igbagbo apapo wonyi, Nigba naa, iwo ki se omo Ijo Onitebomi.”

2. IYASIMIMO

Die lara awon ti won la awon ipele marun-un akoko yi koja le pinnu lati duro ninu Ijo tabi lati ma se bee. A da a nimoran pe ki afi awon ti won ti se ipinnu won han fun Ijo laarin isin. A gbodo ko awon ti a ko ti I se iribomi nipa itebomi patapata fun lekoo si. A gbodo mu ki won fi oro-jomitoro-oro pelu awon adari die ninu awon adari eka Pataki ninu Ijo.

Ni saa kookan a gbodo yan ojo isinmi kan fun fifi awon omo Ijo titun han fun gbogbo Ijo lapapo. A gbodo ka oruko won jade tabi ki a ko won sinu iwe isin Ijo fun ojo naa bi a ba ni. Gbogbo awon diakoni, olutoju ohun-ini Ijo, awon omo igbimo Ijo ati awon kan ti ati yan (Awon alaga elegbe-jegbe, nibi ti o ti ye) gbodo fun won ni owo idapo.

A gbodo mu ki won ka, ki won si fi owo si Majemu Ijo ati Majemu omo Ijo, bi oba wa. A gbodo fun eni kookan won ni iwe ofin Ijo ni gbangba. Bi Ijo ba le pese ounje idapo leyin isin, ko buru.

3. MIMU WULO.

Niwon igbati awon naa ti di omo Ijo, a gbodo gba won niyanju lati darapo mo awon agbo ipejopo, bii ile eko ojo isinmi, kilaasi isonidomo-eyin, ipade atile-dele, abbl. Eyi ni igbanimora. Eni kookan won wa ni ominra lati lo awon ebun emi ati talenti re fun idagbasoke iru Ijo Onitebomi agbegbe bee.

ORO IPARI.

Awon ilana to fanimora wa ti ole ran ni lowo lati gba awon omo Ijo titun mora, awon naa ni a to si isale yii:

a. Igba/ Akoko.

A gbodo ye ohun ti a fe se wo. A gbodo mi ki ilana na rorun lati tele, ikonilekoo naa gbodo je eyi ti o kun oju osunwon.

b. Idanilekoo.

Eni ti n dani lekoo naa gbodo mura sile. Gbogbo awon ohun-elo ikekoo gbodo ti wa nile ki oniwaasu to bere si maa ko awon eniyan jo. Oniwaasu funra re tabi eni ti o yan gbodo fi ara re han gege bi eni ti o mo nipa eto ifinimole awon omo Ijo titun.

d. Sise Pele.

Bi oniwaasu ti n ko awon alejo jo, iwa ibowo fun ipo awon eniyan, eya won lokunrin ati lobinirin, iru eni ti won je, ipilese ati orile-ede ibi won gbodo je e logun.

AWON IBEERE FUN AYEWO ATI IJIRORO.

1. Kin ni a le se lati mu ki gbogbo Ijo dide si ise iwaasu Ihinrere?

2. Kin ni idi ti awon omo Ijo titun fi maa n ko lati lo si kilasi ifinimole, kin si ni a se lati satunse eleyii?

3. Nje o ni awon Igbagbo ti awon omo Ijo dimu, eyi ti o ye ki a se ayewo won? E so iru awon Igbagbo bee ki e si jiroro lori die ninu won.

4. kin ni amuye awon ti won gbodo ko awon omo Ijo titun ni eko isonidomo-eyin.

5. Jeki enikan pin oye re nipa Ogun Ijo Onitebomi pelu kilaasi.

Tuesday, February 1, 2011

GBIGBA AWON ENIYAN SINU IJO PELU IFE (APA KINI)

A ni lati koni ni ona ti a n gba ni ife. O daju pe opolopo Kristiani ko ti I ko nipa bi ati le waasu fun awon eniyan. Ijo nilo lati mo nipa awon aisedede ti o se e ri nipa kiki awon eniyan titun kaabo sinu Ijo. A maa n korin fun won, a maa n pade won ni ara igbalejo, beeni a si maa n ki won terin- toyayani ose meji akoko; Sugbon leyin eyi, enikeni ko ni se aniyan nipa won mo.
Rick Warren, oniwaasu okan ninu awon Ijo ti o ti tobi julo ni ile Amerika kowe pe, awawi ti owoo lati odo awon eniyan ti ki I se ti Ijo nipe, “Awon omo Ijo ki I fa alejo mora. O dabi eni pe akojo eniyan ti n dimo ikoko ni won” o tun wipe, “Awon eniyan yii le maa ro pe Ijo je ajo ‘awon omo egbe nikan.”
A ko le se iyemeji nipa otito naa pe opolopo awon ti won n wa sinu Ijo le ma ni oye awon afaani ati ojuse jije omo Ijo. Eyi le je okan ninu awon ohun ti n di ifara-eni-jin won lowo. Nitori naa, a gbodo ran won lowo lati dojuko awon ipenija naa, lati bowo fun ojuse won, ati lati gbadun awon eto ti o w ninu jije omo Ijo.
ISORO AWON OMO IJO TITUN.
Ohun ti o wa loke yi toka si wipe orisirisi ni ogun awon omo Ijo titun ti n wa sinu Ijo.bakan naa, Nitori ipile won ninu asa ati jie omo egbe, a ni lati gba won sinu Ijo lekunrere. Gbogbo wa nilo lati ni imolara irora ti die ninu awon omo Ijo titun ti o le ni irewesi okan, ti ko si ni imolara jie omo Ijo rara n ni, nitori pe won ko ni oye awon ede, ogbon isejo awon asa ati ipo liana Ijo naa. Nitori idi eyi, ifara-eni-ji won ki I kun.
Ijo ti o ni ife nikan ni o le yi “awon Amagagbon” pada si “ awon olukoni.” Gbogbo awon omo Ijo titun gbodo je okan ninu awon ti n kekoo Bibeli ninu agbo ifinimole tabi Isodomo-eyin. Iru eko naa ko gbodo pe lo titi, o si gbodo ni ilan ti a la kale daradara, lai fi aaye pupo sile fun iyato. Leyin iru itoni bee, a o pe eni kookan nija lati sawari ebun re ni pato ki o si lo o bi o ti ye. Ijo agbegbe kookan gbodo se agbeyewo awonona ti a la kale nisale yii.
1. IHINRERE
Ijo kookan gbodo ni igbimo Ihinrere. Ni ibamu pelu ilana, ajo tabi ifilele ofin, awon omo egbe iru igbimo bee ko gbodoyo awon osise Ijo wonyi sile:
 Oludari Ihinrere
 Oludari ise-iranse adura.
 Awon omo egbe ise-iranse ibewo.
 Oludari egbe oludani-nimoran.
 Awon osise Ihinrere ti egbe Okunrin onihinrere/ Egbe obirin onihinrere/ egbe odo /egbe akekoo Ijo onitebomi .
 Diakoni kan
 Ojise Olorun fun Ihinrere
 Oniwaasu Ijo.
Igbimo naa gbodo seto iwaasu Ihinrere kaakiri agbegbe naa. Ti ise-iranse adura ni lati ro won lagbara pelu aawe ati adura. Saaju akoko ti won yoo jade lo, a gbodo gbadura iyasimimo fun won ni ibi ti won yoo lo fun iwaasu ita gbangba naa. Oludari awon oludani-nimoran gbodo ko awon omo egbe re jo lati mura sile fun sise ise-iranse fun awon ti yoo dahun si awon ipe naa. A gbodo samulo ise-iranse fiimu ati iwe iwaasu pelebe lati sasepe iwaasu atile-dele.
Nibi ti a ti le ko owo jo, a gba wa ni imoran pe ki a jumose tabi Ijo kookan ra ero amaworan tobi (Multimedia Projector) ati ero ti n gbe aworan Jade (DVD player) fun ilo ise-iranse Ihinrere. A gba oniwaasu tabi eniti o ti yan niyanju lati ko iwe iwaasu pelebe naa ni ibamu pelufiimu ti won yoo fi han awon eniyan naa. Awon odo ati egbe Akekoo Ijo Onitebomi ni a gbodo dari lati lo siwaju Ijo ki won le je ki olugbe ibi ti a ti yan fun iwaasu naa mo nipa eto naa nipa pinpin awon iwe iwaasu pelebe. A gbodo tanmole, ki a si so fun ay nipa Olorun ife ti I maa fa awon elese mora, Sugbon ti o korira ese.
2. AJOYO.
Gbogbo isin Ijosin ninu Ijo Onitebomi gbodo je ajoyo jije Oluwa Jesu Kristi ati Ijolotito Olorun. O gbodo pese anfaani fun awon eniya lati ni iriri iwa laaye Emi Mimo, oluranlowo ati olutunu wa. Ninu iru jije bee, akowe Ijo tabi diakoni kan ni o gbodo koko ki enikeni ti oba pinnu lati ba won josin tabi ti o ba pinnun lati wa darapo mo Ijo naa kaabo leyin ifilo.
O to ki a so ni ibi yii pe, a ko gbodo ka eniekeni si alejo pon-n-bele. Eyi ri bee nitori pe, ni Pataki julo, awon alejo wa ni abe idaabo bo jije ti Olorun je baba. A le samulo iru awon oro bayii:
“Ile Baba yin ni e wa. Bi e ba n josin pelu wa tabi ti e ba n pinnu lati darapo mo Ijo yii, e jowp e dide duro, ki a le moyin. Nigbati isin n tesiwaju, oniwaasu wa yoo tubo ki yin kaabo.”
A gbodo fun alejo kookan ni iwe isin Ijo, iwe orin;bi alejo naa ko ba ni tire, ti ki si se pe ati fi okan si ori aga Ijoko re tele, ati Bibeli kan; bi alejo naa ko ba mu okan wa. A gbodo dari awon ti won joko si egbe awon alejo na lati ki won gege bi isafihan ife, itewogba, ati iyomoni.
Gbogbo Ijo gbodo se ayesi enikeni ti n darapo mo Ijo naa pelu ebo ope si Oluwa, ati orin ikini-kaabo.
3. IPE.
Leyin isin, awon omo egbe ibewo tabi awon omo egbe oludani-nimoran Ijo naa gbodo jokoo ti awon alejo naa, won gbodo fi oro-jomitoro-oro pelu won, ki won si gbadura fun won ni yara alejo tabi ibikibi ti a ti seto fun ete yii. Won gbodo so nipa Ijo naa fun awon alejo yii, ki won si fun won ni iwe ti nsoro nipa Ijo naa. A le fun won ni ipanu die, a le gba won laye lati bere ibeere, ki a si gba won niyanju lati fie be adura sile, bi won ba ni. Adura ni a gbodo fi parieto yii.
Eto naa gbodo je eyi ti o fanimora, a si gbodo fiyesi imolara, akoko ati iru eya awon alejo naa lokunrin ati lobinrin. Gege bi apere, a gbodo bowo fun iyawo ti oko re ko si ninu Ijo naa bi a ba beere fun iyonda lati tele lo sile. Aifarabale re gbodo ye wa.

4. IBEWO
Laipe ojo a gbodo fi ikini ranse lori ero algbeka, a gbodo pe won, ki a si be won wo ni ile won. Diakoni tabi enikeni ti a yanlati be awon ti a n fojusun fu alti di omo Ijo na wo gbodo je eni ti o mo dada nipa itan, ogbon itojo, awon ofin, ipinfunni/isakoso, ilana ati itoju ti Ijo naa ni leto fun awon ti n josin nibe. O gbodo le da-n-to, niwonba, lati jiroro lori awon aini ati iriri Ijo. Ju gbogbo re lo o gbodo ni oye oro Olorun.
A damoran ki diakoni kan,Oluko ile eko ojo isinmi kan, oludari Isin atile-dele kana abbl. Se ise yii. Awon ohun ti won woye, iwadi ati Iroyin lati ibi ibewo naa ni won gbodo fifun oniwaasu ki o le sise le e lori.

Thursday, January 27, 2011

WIWA TI EMI MIMO

Ise Awon Aposteli 2:1-13
Ki a to kan Jesumo agbelebu, ki o to gun oke lo si orun, o seleri wiwa EMI-MIMO fun awon omo eyin re. Nigbati Emi naa ba si de, oun yoo maa je Oludamoran ati Olutunu ayeraye fun won (Johanu 14:15-16, 16:17); Olutonisona ododo nigbagbogbo (Johanu 16:13); ati agbara fun itankale ihinrere ni gbogbo agbaye (Ise awon Aposteli 1:8). Ninu ipin ibi kika wa a ri imuse dide ti Emi olorun naa ti oti se ileri. O ye ki o ye wa nibe pe isele ti o sele ni ojo Penticosti yi ko tumo si ibere Emi Mimo. Ise ati imisi Emi Mimo fi ara han pupo ni akoko Majemu lailai naa, Pataki julo ninu itan ile Isreali. Sugbon iyato ni eyi: ninu Majemu Lailai, awon Woli, Awon Alufa, ati awon oba nikan ni agabra Emi Mimo ngbe wo ti o si n lo won. Sugbon ni ojo Penticosti ni a ti fi agbara ati imisi fun gbogbo awon olotito ati olugboran omo eyin Jesu.
Beeni, inu awon ti o ti di atunbi nitooto ninu Jesu nikan ni Emi. Ninu ipin bibeli ti a ka, a o ri wipe awon ti a fi Emi mimo fun ni awon ti ko dale Jesu ni gbogbo igba ti ogun le. Nisisinyi naa pelu, won tun ti setan lati tesiwaju ise nibi ti Jesu ti da duro. Won duro nibi ti won ni ki won duro si (Luku 24:49; Act 1:4-5; 2:1)