Tuesday, June 21, 2011

IMO, IGBORAN, ATI JIJE ALABUKUN – FUN.

Bi eyin ba Mo nkan wonyi, ALABUKUN – FUN ni yin, bi enyin ba n se won.

Gbolohun ti wa ni oke yii ti enu Jesu Kristi jade leyin igbati o ti ko awon omo – eyin ni sise ise isin elomiran ati iyi ti o wa leyin re ninu Johanu 13:1 -17. O je ki oye won wipe ise Pataki ati jije eni iyi duro lori iwa irele ti a ni lati le sise sin elomiran. Sugbon eko wa duro lori awon oro Pataki meta ti a ri ka ninu ese ketadinlogun. Awon oro meteta naa ni: Imo, Igboran, ati alabukun – fun.

IMO nibiyi tumo si:

  • Imo Olorun otito – Abuda Re, iwa Re, ati ife Re.
  • Imo oro Olorun ati igbekele re, Pataki julo awon ipin ti o so nipa igbala.
  • Imo nipa ara eni gege bi eniti o ti subu sinu ese ti o si nilo iranlowo lati dide (Romu 3:23).
  • Mimo Jesu Kristi gege bi Omo Olorun tooto ti a ran si ofun igbala emi re (John 3:16)

IGBORAN tumo si:

  • Bibowo fun ife Olorun ati gbogbo ofin Re.
  • Sise ife Olorun, ti ki n se ti asehan tabi nitori ere ti a o rigba nibe, sugbon lati inu emi irele ti ogbooro.
  • Titele ase Olorun, ti ki n se nitori ti o tele aigboran, sugbon lati inu okan ti o n fi emi ife han si Jesu Kristi.
  • Jije olotito titi de opin. Eyi tumo si igboran nigba gbogbo ati ni gbogbo ona.

ALABUKUN fun je ayorisi imo ati igboran. Lara re ni:

  • Ibale okan lai si rudurudu tabi iporuru okan nigba kankan. (Mattiu 11:18)
  • Alaafia lati inu ati eri okan daradara pelu Olorun ati gbogbo eniyan.
  • Wiwa laini ebi okan, irunu, ati inu buruku si enikeni. Eyi tumo si idunnu ati jije eni itewogba niwaju Olorun.
  • O tun tumo si ire, aanu, isegun, igbala, ati ireti ti ko nipekun.
  • Oore – ofe ti o to ati ibewo lati oke wa ni asiko aini (2 Korinti 12:9)

IPAARI.

Jije alabukun – fun lati odo Olorun ko ni nkan se nipa jije omo ijo tabi jije olusin ni gbogbo igba. Ko si ni nkan se pelu ohun ti eniyan je ninu ile Olorun tabi ise ti eniyan n se ninu ile Olorun. Sugbon jije alabukun – fun lati oke wa duro lori MIMO ati SISE ife ati ase Olorun. Jesu wipe Bi eyin ba MO nkan wonyi, ALABUKUN –FUN ni nyin, bi eyin ba n SE won.