Friday, October 5, 2012

AWON EROJA FUN IDILE ALAYO

AWON EROJA FUN IGBEYAWO ALAYO.

Eroja Kinni: ISOKAN.
(Orin Dafidi 133; Amosi 3:3)
Ai si isokan je ohun ti a ko le ye sile ninu idile Sugbon isokan je ipo ni bi ti awon meji ti igbagbo won ko tako ara pade pelu gbigba fun ara won. Isokan maa n sele nigba ti oko ati iyawo  ba pin ero oto., iwa, tabi ete oto Sugbon ti won gba lati fi iyato yii sile tinutinu won fun ara won lati mu ki ete ero kan naa se nitori igbeyawo won.
Bi a se ka ninu Bibeli o fi han wa pe Olorun feran isokan (Orin Dafidi 133:1). Eyi fi han wa pe lai wo gbogbo ohun ti n sele, oko ati iyawo maa n se afihan ki n kan wa leto leto ninu ile won. Ai si isokan maa n tu ile ka Sugbon isokan maa n fun ile lookun si ni.
KINNI AWON IDI TI AEINI ISOKAN SE MAAA N WAYE?
Awon idi wonyii ni o maa n fa aini isokan ninu igbeyawo eyi ti Adeola Adeniyi ko ninu iwe igbeyawo laisi wahala:
1.   Iwa Eniyan ti o yato si ara won da lori ipile iriri enikookan ninu idile ti oko ati iyawo ti wa.
2.   Igbe aye sekarimi: aini isokan maa n wo inu igbeyawo nigbati  oko ba tako rira aso igbalode eyi ti o le ni ipalara   lori oowo ile iwe awon omo. Sugbon ti iyawo ko ri ohun ti ko dara ninu re.
3.   Ife ara eni: (Esteri 1:7 - 11) wahala maa n bere ninu ile nigbati oko tabi iyawo baro wipe oun le se ohunkohun lai se pe won to sona.
4.   Ifaga gbaga: (Esteri 1:2,5 ,8): wahala maa n sele ninu igbeyawo nigbati oko ati iyawo ba ri ohun ti won ni bii – owo, iwe eri, ewa – bi ohun ti won fi ju ara won lo
5.   Gbigba imoran lowo awon ti ko to (Esteri 1:13, 15).
ANFANI ISOKAN.
1.   O maa n mu itesiwaju wa (Genesisi 11:5-8)
2.   O maa n mu ki ota jinna si ni (Deut 32:10)
3.   O maa n mu Ibukun Olorun wa (Orin Dafidi 133:3)
4.   O maa n yori si ayo ati ifowosowopo (Amosi 3:3).
Ibare ninu igbeyawo seese nigbati oko ati iyawo ati won omo ba ni, ti won si bowo fun ilana eyi ti o ndari ona ti won fi n huwa, woso ati dojuko awon Akoko ti onira ninu igbeyawo.
    Ara ni eya orisirisi  bi o se n sise sibe won n sise papo lati mu ki ete kan na wa si imuse. Bakan naa oko ati iyawo ti o nife igbeyawo alayo gbodo ri ara won gege bi ara pelu eya ara orisirisi ti o nsise papo lati mu ki ete kan wa si imuse.

Eroja keji: ITOJU.
(Efeseu 5:28 -29, 6:4)
Itoju pe fun kike eleomiran pelu ete ati fifi ife ati iwuri han si elomiran. Itoju ninu igbeyawo bayi se afihan ohun ti enkeji eni nilo ati biba awon aini yii pade. Lati mo bi a se toju ara wa, oko ati iyawo gbodo mo pe awon aini won yato ati ona otooto ni a le fi ba won pade;
Lakoko, e je ki a wo awon aini obinrin eyi ti oko gbodo ba pade;
1.   Obinrin nilo ife ati iwuri: Ninu iwe igbeyawo ti o  sise, Pelt so wipe obinrin kookan nilo idaniloju pe ife oko oun je ife aisetan ati eyi ti o fi han lojoojumo. Ohun ti eyi tumo si fun Okunrin ni pe ki won pinnu lati fi ife ati iwuri yii sinu ise nipa rirerin, didi mora eni, mimoriri ati fi feti sile nigba gbogbo.
2.   Obinrin nilo aabo lori imi edun: Iwadi tun fi han pe opolopo obinrin fe idaniloju pe oun gba ibi Pataki ninu okan oko re. Pelt so wipe obinrin le so fun oko re lati se ohun kan eyi ti o le se funrare pelu irorun. Ohun ti eyi tumo si ni pe ki oko kookan ma fihan iyawo re pe leyin Olorun, oun ni o tun gba ipo Pataki.
3.   Obinrin nilo imoriri fun igbiyanju (Ise)inu ile: Iwadi se afihan pe obinrin fe ki oko re mo iriri re fun titun inu ile se. Ohun ti awon Okunrin miran ko ka si. Eyi tumo si pe oko gbodo maa ki iyawo re ninu ohun “kekere: ti o ba se.
4.   Obinrin nilo imoriri fun igbiyanju titun ara Re se lati Dun – un wo: Olugbani nimoran lori igbeyawo kan ko bayi pe obinrin nilo opolopo idaniloju pe o si dun wo lai wo bi ojo ori re se to. Okunrin gbodo maa mo iriri bi o se ri, aso ati bata re.
Eko yii tun se agbeyewo lori aini imi – edun ati ti ara ti  awon awon obirin ey ti Okunrin gbodo ba pade.
Ifiyesi: E jiroro lori aini ti owo, ti ero ati ibakegbe ti obinrin eyi ti oko kookan gbodo ni oye re ki o ba le mo bi yoo se boju to.

Ni ona miran, obinrin kookan ti ofe lati toju oko re gbodo koko mo awon aini Okunrin kookan.
1.   Okunrin nilo owo (Ibowo fun) (Efesu 5:22) Ibowo fun je lati moriri oun ti o je. Onimo igbaninimoran lori igbeyawo se awari pe Okunrin nilo latari mo pe iyawo oun bowo fun on ni ona ti iyawo naa n gba soro, ni ona ti o ri gba wo gege bi olori ile.
Ijiroro: Se ki oko maa gba ibowo ni tabi ki o maa bere fun?
2.   Okunrin nilo gbigba iyi fun imura, agbara ati iwa Re.
   Imura tabi iriri Re: inu Okunrin maan dun ti iyawo re ba yin iduro re. kin ni idi ti opolopo
obinrin Kristiani kii fi yin imura oko won?
   Agbara: Nigbati iyawo ba se ajoyo lori oye ati talenti oko re, aseyori lenu ise yoo po si fun iru
oko yii.
   Ihuwasi: iyawo ti o ba mo riri ifarada oko re yala ni ti wahala eto isuna ti opolo ni gbigbiyanju
lati ba aini inu aye iru oko naa pade.
Itoju se Pataki ninu idile Kristiani loni nitori orisirisi ogun ni o wa fun oko ati iyawo Kristiani kookan eyi ti o le nipa lori ife Akoko won. A maa mu ife dara si nigba ti oko ati iyawo ba mo awon aini won ti won si baa pade pelu iwa pele.

Eroja Keta: IFIFUNNI.
(Romu 8:32; 11:35)
Odi igbekele maa n wo lule ninu ilekile nigba ti oko tabi iyawo ba lahun. Ififunni je ajosepo igbeyawo eyi ti o pe fun fifi ohun ti oko tabi iyawo ba ni sile ki o ba le ba aini ara won pade ati leyin naa gbe idile alayo kale. Ni oro miran, igbeyawo pe fun ififunni.

Ni idi ti ififunni se se Pataki ninu igbeyawo Kristiani?
O se Pataki nitori ajosepo ati ifara eni sile ninu igbe aye igbeyawo toka fun aye ajosepoti o wa laaarin Kristi ati Ijo. Jesu, oko iyawo fi gbogbo re sile de oju iku ki o ba le se afihan ife Re si Ijo (Iyawo). O tun toka si pe oko ati iyawo ti se awari pe ohun ini won ni a fi fun won lati mu ki idile won dagba. Bakan naa ififunni pelu ifarajin se afihan pe oko ati iyawo ti ri ara won bi ara kan ti ko se pinya bayi, ohun ti won ni je ti awon mejeeji

Awon Ohun ti o ye ki oko ati iyawo fi fun ara won.
Ko si oko ati iyawo ti ko ni ohun kan ti oye ki ofi sile lati mu ki igbeyawo won dara si. Die lara awon ohun ti o ye ki awon oko ati iyawo pin pelu ara won ni:
1.   Akoko / Ifetisile: Opolopo Akoko maa n pese anfani lati fikunlukun tabi pin isoro, ero, eru papo
ati salaye aigbora eni ye funra eni.
2.   Owo: owo maa n pese anfani lati ba aini ti isuna ti enikookan pade
3.   Ara: Se e maa n fi ara yin sile lati te ife ibalopo lorun fun ara yin?
4.   Ero / Oro: Se a maa n ronu papo tabi fun ara  yin ni imoran eyi ti o le ran ipinnu idile wa lowo?
5.   Ebun: Se a maa n fi ebun fun ara wa alsiko ojo ibi, ayeye ikeko jade abbl.
Olorun je olufifunni. O se agbekale igbeyawo ki a ba le mo bi a se n pin gbogbo nkan pelu ara wa. Aami miran fun idile Kristiani ni lati fifun elomiran.
1.   Fifi fun Olorun.
2.   Fifi fun awon alaini ati opo.
3.   Fifi fun awon omo yin.
4.   Fifi fun awon omo alailobi.
5.   Fifi fun awon oniwaasu.
6.   Fififun ise Ihinrere.
IFIYESI.
1.   Owe 31:16, 20 se apejuwe obinrin gege bi olufifunni. Kin ni idi ti o fi maa n soro fun opolopo obinrin lati fifun oko won ati awon oko lati fifun awon iyawo won?
2.   Kinni ipa ti iyawo / Oko ti o ba je  ahun maa n ni lori awon omo?

Eroja Kerin: ITERIBA
(Genesisi 3:16, Efesu 5:21, Romu 10:3)
Iteriba kii se siso ohun ti eniyan je nu tabi maa gboran bi afoju si awon alase. Itumo iteriba ninu majemu titun je nigba ti “eni kookan ba teti si ero tabi ife ara won” tokantokan nigba ti ero won ba tako ara won. O tumo si pe iteriba ninu igbeyawo Kristiani ko so oko di olori nibi ti yoo ti maa pase ti iyawo re yoo si teriba bi eru (ati ni idakeji pelu) (Efesu 5:21). Gege bi Pelt se ko, Jesu Kristi teriba si ife Baba re sugbon eyi ko je ki o je alaitegbe nigbati o teriba.

Kinni awon ise Pataki iteriba.
Pataki iteriba ninu igbeyawo fi idaniloju idari Olorun ninu ile eyi ti o maa n mu ki ibare wa. (Korinti kinni 11:3,8,9,11,12). Ete miran ni ki iyawo le ri iteriba bi iwa eyi ti o n fi ibowo fun Olorun han.

Bawo ni eyi se n sise?
1.   O maa n sise nigati awon took –taya ba ri ara won gege bi egbe niwaju Olorun pelu eto lati se ipinu pelu ogbon.
2.   O maa n sise nigbati took –taya  ba dowo fun ero ara won Sugbon ti won ko ko maa figagbaga.
3.   O maa n sise nigbati iyawo ba n mo pe oko ohun nife, o si gba oun. (Efesu 5:25)
Tani oko ati iyawo ye ki o teriba fun?
Amin Ife Olorun Akoko ninu igbeyawo ni iteriba si ife Olorun (Deuteronomi 6:5). Won gbodo tun bowo  fun awon adari emi, ijoba, awon obi ati fun ara won. (Efesu 5:21)

Iteriba maa n fi aaye biba ara eni soro daa sile at leyin naa se ipinu ti o mogbon wa ati eyiti to je okan lara iwa rere fun idile alayo.

IFIYESI:
1.   Jiroro lori awon idi ti aini iteriba se wa ninu idile Kristiani ati ona abayo.
2.   Kinni awon ipa ti aini iteriba fun ara eni ns e wa laarin oko ati iyawo.

Eroja Karun: IBARE NINU ORO.
(Kolose 3:12 – 17, 4 – 6)
Opolopo oko ati iyawo ni won nife lati maa pin ohun ti o nse won ati aini won pelu ore, awon ti a jo n sise ati awon ana won ju ki won pin pelu enikeji won lo. Sugbon Gary Smalley, eni ti o je onimo ninu igbeyawo so wipe ibare ninu oro le wa ninu igbeyawo nigbati oko ati iyawo ban pin aini ati ohun ti n won n la koja pelu ara won. O je okan lara kokoro si ifarada ninu igbeyawo. Ki oko ati iyawo le ri ara won bi ore ti o se gbekele ti won le ba soro.
Oro siso papo eyiti o jinle ni awon ete yii:
1.   O maa nfaye sile fun sisoro ti odan moran lori ohun ti o jeyo ki oye ba le wa.
2.   O maa n jeki igbagbo odi di mimo si ara eni.
3.   O maa n je ki adura won di didahun. Idile ti o ba n soro papo maa bo lowo gboyi soyi.
4.   O maa nje ki awon omo, ana ati adugbo bowo fun awon ati igbe aye won je eko fun elomiran.
Bawo ni sisoro papo se le sise
Awon ona ti oko ati iyawo ti o fe ayipada ninu bi won se n ba ara won soro le lo eyi.
1.   ki won gba ara won gege bi ore.
2.   Feti silesi awon ami ibara – eni – soro si ara eni. Awon itumo miiran le wa ninu ohun ti o n so bi
ihuwa, aso ati iri wa.
3.   Maa lo oro rere. Ma maa siregun tabi bu eebu. Awon oro nipa awon Okunrin ati obinrin alagbara fihan pe oro ti awon enikeji won so lati gba won niyanju lo so won di alaseyori.
4.   Maa fi imi edun re ti ko dara han ninu ife. Faye gba Emi Mimo lati kapa ibinu ati ikoro re ki ibinu
ati ikoro ma baa ma dari re.
5.   Maa bere ibeere. Ma fa seyin nigbati e ba ja. Maa lo oro bi “awa” dipo “iwo” lati toka alebu
enikeji re.
Idile Kristiani gbodo faaye gba Emi Mimo lati je ti won. Soro daada pelu ife ati pelu otito inu. Won gbodo faaye gba siso ero won lai si iberu lori ohun gbogbo ti oba jeyo. Awon oko gbodo maa soro pelepele pelu awon aya won. Awon omo gbodo kopa ninu adura ati ipinu idile. E ma gba awon omo niyanju lati maa so ero won aliberu, eyi yoo mu ki won ni igboya. E maa ko won ni ona ti won yoo lo ti won ba dagba won yoo le soju yin ati Olorun daadaa. (Owe 22:6). E jowo asise yin, e darijin ki e si maa gbadura fun arayin. Ni sise eyi igbekele ati isokan yoo wa ninu idile .
    Ona ti o sise julo ni biba ara eni soro ni bi a se n gbe igbe aye wa. Ise wa soro ju oro enu wa lo.

IFIYESI.
1.   Kinni idi ti opolopo oko ati iyawo kii se ba ara won soro nigba ti won ba ja?
2.   Kinni ipa ti eyii maa n ni ati ona abayo.

Eroja kefa: IDARIJIN.
(Matiu 6:12 – 15, Isaiah 43:25 – 26)
Itumo idarijin Akoko ni lati tu eniyan sile. Eyi tumo si pe nigba ti oko ati iyawo ba ni ikoro si ara won, oko ati iyawo so ara won pelu okun ni yii. Ija je ohun ti a ko le ye sile ninu igbeyawo. Sugbon o maa n jeki oko ati iyawo pa ara won alara. Eyi si le je okankan ninu oko tabi iyawo fi ibinu pamo si ara won eyi si le je ki pipari ija soro.
Bawo ni aini idarijin se n sise
Ona ti aini idariji se nsise ninu igbeyawo ni ngbati yala oko tabi iyawo ba n dibon bi eni ti ko ni ipalara gege bi esi si ija ti won ja Sugbon ti on se afiha re ninu ise re nipa.
1.   Bibinu lori imubinu kekere kan.
2.   Siseregun
3.   Fifa seyin tabi didake
4.   Aifowosowopo
5.   Iwa ti ko je itewogba
6.   Ikosile
Ipa yii maa n mu ki aifokan bale wa ninu ile.

Bi idariji se n sise
Idariji maa n wo ajosepo san. Gary Smalley, Onimo ninu igbani nimoran lori igbeyawo se afihan awon igbese die yii:
1.   Faaye gba igbonara re ki o tutu lati gba ogbon ati oye si isoro naa ki e to jiroro le lori.
2.   Faaye gba eni ti a se lati banuje. E soro nipa sioro naa fun ara yin ki e fi gbogbo re sile fun Oluwa.
3.   E wa eko ninu ese naa ki e maa ba tun se asise yii mo .
4.   E tu eni ti o ba se yii sile ju ki e gbiyanju lati gbesan lo (Romu 12:19). E gbadura fun ookun
Olorun lati le je ki e laannu eni ti o se yin.
5.   E toro aforiji lowo ara yin. E wa awon ona ti o le se iranlowo ni wiwo eni ti o se yan san.
Awon ona yii wa fun eniti o se ti osi gba a si asise re ati ti o si setan lati se atunse. Eni ti a se gbodo mo pe a ti dari ese re jin nigba kan ri nipase Olorun.

IFIYESI.
1.   Kiyesi esekese eyi ti o n fi pamo fun oko tabi iyawo re ki osi jewo re pelu oye Olorun loni.
2.   Eyin omo, se e ni ohunkohun ninu okan si awon obi yin? E so loni ki e si darijin won Olorun yoo
si sure fun yi.
3.   E gbadura fun awon eniyan ti o se yin Sugbon ti won ko beere fun idarijin. Bi o ba ssese e so fun
ki e si darijin won.

Eroja keje. ADURA IDILE.
(Dueteronomi 6:4-9; Orin Dafidi 1:2 – 3)
A maa n saba ro pe aseyori maa n wa ninu oko tabi iyawo ti o rewa, ise ti o dara, ore, owo ile tabi ipo. Otito ni pe nigba ti ipenija ba de awon nkan yii ko le duro ayafi Olorun ti o je orisun agbara ifarada (Matiu 6:9 -21). Nitori naa, a nilo lati wa agbara atoke yii eyi ti yoo maa so igbeyewo wa ji.
    Adura idile bayi maa n pese aaye fun Olorun Eleda Eni ti o da igbeyawo sile lati soro ba wa wi, bukun ati to oko ati iyawo ati awon omo sona lojoojumo. Ko si eni ti o koja asise.
Idi ti adura idile fi se Pataki
1.   Igbeyawo kii se ero eniyan (Genesisi 2:18 -23)
2.   O maa n daabo bo idile lowo igbogun nitori ota maa n wa ona lati tu idile ka. (Genesisi 3).
3.   O maa ntun okun oko ati iyawo ati awon omo se lati ni fe ara won lojoojumo (Isaiah 40:31)
4.   O maa n fun idile ni oye ilana Olorun titun fun ojo kookan (Deuteronomi 6:7 – 9)
5.   O maa n nipa lori awon omo lati ni igbagbo ninu Olorun ni ibere aye won (Orin Dafidi. 71:18,23)

Bi adura idile se e le sise.
1.   E ji laaro kutukutu lati bu ola fun Olorun fun ojo titun.
2.   E sin Olorun ninu orin.
3.   Elo akoko pelu Olorun ni kika oro Re.
4.   Sasaro lori oro Olorun, ki e si pin itumo re pelu ara yin.
5.   E dari idile lati ko ese Bibeli sori.
6.   E ni iyara eni sapakan opin ose.
Idile ti o ba gbadura papo yoo wa papo. Idile kookan nilo iwalaaye Olorun lojoojumo lati koju ipenija ojoojumo

Koko adura
1.   Oluwa ran mi lowo lati mu ohun ti o ti seto fun mi ati enikookan ninu idile mi se ni oruko Jesu
2.   Ran wa lowo gege bi idile lati ma sina.
3.   Oluwa ran wa lowo lati pa ogun ini wa mo eyi ti o je fifesemule ninu Re.

A tee eko yii jade lati le ran Idile Omo Ijo yii kookan lowo, ki o si  le e ro Idile kookan lagbara sii. Nitori naa bi E ti n lo o, E ko eko, ki E si gba ipenija ninu re lati fi se atunto eeto Idile yin. Esu atomogun re ko ni ri aye ninu Idile yin. Leyin aye yii, eto Idile wa ko ni mu wa sina Ijoba Olorun.