(Hosea 6):
(Vs.1 – 3) – Se afayo bi awon Omo Israeli se gbe etan kale ti o jo ironupiwada won si Olorun.1. Nwon pe ara won lati yipada si Oluwa, nitori ti o ti fa won ya.
2. Ki Olorun le mu won larada, nitori ti O ti lu won, yoo si tun won di.
3. N won ni leyin ojo meji, Olorun, yoo so won ji, ni Ijo keta yoo gbe dide, awon yoo si wa niwaju Oluwa.
4. N won ni, nigba naa ni awon yoo mo bi awon yoo ti tera mo mimo (knowing) Oluwa.
5. N won ni, Oluwa, ti pese ijade bi owuro, yoo si to won wa bio arokuro ati akoro ojo (rain).
(Vs. 4 – 11) – Se afayo bi Olorun se ri igbese etan ti o jo ironupiwada ti awon Omo Israeli gbe.
1. Olorun bere, Efraimu, kinni emi o se si o, Juda, kinni emi o se si o.
2. Nitori ife awon Omo Israeli dabi ikuuku owuro ati bi iri kutukutu ti o koja lo.
3. Nitori naa ni Olorun se fi aake ge won lati owo awon Woli nipa oro enu won ati idajo ti o rii bi imole.
4. Nitori naa Olorun ni ikanu ni Oun fe, kii se ebo ati ki n won ni imo Olorun ju ore ebo sisun lo.
5. Bi Adamu, won ti da majemu Oun, (Olorun) koja, bee ni nwon si ti setan.(deceit and unfaithful)
6. Gileadi ni Ilu awon ti n sise ese ti a si fie je baaje.
7. Awon alufa fohun sokan lati paniyan, lona sekemu, bii owo ole ti n humo de eniyan lati te siwaju ninu iwa ipa.
8. Olorun ni Oun ri ohun buburu kan ni ile Israeli, Efraimu ati isreai ti fiwa agbere ba ara won je.
9. Juda ni Olorun ti gbe kale fun ikore nigbati Oun Olorun ba yii igbekun re pada.
Akiyesi.
1. Lati Ibere aye ni OLUWA, Olorun ti korira iwa etan, arekereke, iro a.b.b.l Iwa ti Olorun korira ni awon omo Israeli ati awa naa loni fi n ba Olorun lo. Eyi ko si le ran wa lowo (Jakobu 5:12)
2. Bi awa naa, awon Omo isreali ko mo odiwon iwa ese agbere won si Olorun, won ro wipe leyin ojo bii meji tabi meta ti awon ba fi wa oju rere Olorun tito (boya ki won o tun le pada si iwa agbere won). Lodo Olorun, eyii ko je nkan bi ko se ironupiwada patapata lo le wa ni ibamu lati yii idajo idalemi Olorun pada -V. 6 (Matt. 9:13; 12:7).
3. Bi inu Olorun ko ti dun ki elese kan ku sinu ese re, bee yoo tete tewo gba ironupiwada ti o jile ti elese kan ba se. (Apere Ilu Nenefe)
4. Nitorina loni, Eko yii n ko wa ki a ma gbon loju ara wa, Sugbon ka a ni irele okan ti o le mu wa ba ojurere Olorun pade ti o si le mu wa di pupo fun rere ninu ohun gbogbo (Mika 6:8).
Akoko Adura.
1. Mase jeki n josin labe Orun titi. Ise Isin mi, akoko Isin mi ati edawo ninu Isin mi ko gbodo jona
loruko Jesu.
2. Oluwa ran mi lowo lati le maa fi okan irele tele O ati ki aye mi le wulo fun O loruko Jesu.
3. Awon Omo Israeli je apere ti ko dara lati tele, jeki agbara ti muni je alapere re wonu mi loni loruko
Jesu.