Thursday, May 16, 2013

ERE IJOLODODO




Ifaara:             Igbe aye igbadun eni maa n soro gan – an ni lati fi sile, Eniti o ni oko tabi ohun irinna miran; eniti o ni Ile, ti ko wa ni mo; eniti o ni ise lowo ti ko wa ri ibikankan lo mo a.b.b.b.l  bi iru eni bee ko ba ni AJE – ARA (Immunity), o le di elomiran (Onidajo 16:17 --- alaelera, emi si dabi Okunrin miran)      
Bibeli Kika    (Romu 6:15 -23)


(Vs 15 -18). Se afayo bi Kristiani se ri labe Oore – ofe, ti ki si se labe ofin.
a.       Nitori ti a wa labe oore –ofe ko wipe ki a maa dese – (V15).
b.      Nitori ohunkohun ti a a ba yonda fun la o maa gbo lati se tire
c.       Bi a ba yonda ara wa fun ese le yorisi iku, ofin ni yoo si se idajo ara (v16)
d.      Bi a aba yonda ara wa fun igboran le yorisi ododo, oore – ofe yoo si mu wa duro
e.       Oore – ofe ti so wa di ominira kuro ninu ese, ki i se labe ofin ki a le maa se ododo (Vs. 17 18)

(Vs. 19 – 23). Se afayo bi Omoeyin Kristi se le gbe igbe aye ododo, ti o le soo di olododo.
1.      Bi awon iwa ese ti ndun mo o, bee gege ni yoo di eru si igbe aye ododo ninu Kristi – (V19)
2.      Bi a ko ti mo Omo-eyin Kristi nigbati o wa ninu ese, bee gege la o mo o ninu ododo – (V20)
3.      Bi a ko se tiju ninu ese dida, bee gege la ko gbodo tiju lati gbe igbe aye ododo – (V.21)
4.      Bi a se so wa di ominira kuro ninu ese, bee gege eso iwa mimo wa yoo yori si iye aenipekun (V22)
5.       Bi iku se je ere fun es, bee gege ebun Oofe Olorun yoo je ere si iye aenipekun – (23).

AKIYESI.
1.      Eko wa oni n laaye wa wipe - eniti a n ba ngbo tire ni yoo je oga, aladari tabi alase lori aye wa. Bi o ba je owo, owo ni yoo maa dari wa tabi bi o ba je nkan miran nkan miran bee ni yoo ma je oga ati alase lori aye wa.
2.      Eko yii n ran wa leti wipe gbigba ti a gba wa la. Oore – ofe lati gba wa la kii se ofin tabi ise ti a ba maa fi sogo (Efesu 2:4 - 9)
3.      Bi ofin ba n sise idajo, idalebi, ti oore –ofe si n sise idalare. O je wipe ebun oore – ofe yii di ohun elo iwa si ododo ti o le so wa di olododo ki a le jere olododo (Matteu 10 :40 – 42; Heb. 6: 9 -12)
4.      Gbogbo eniyanloni ominira lati yan eyiti o wu – u. Olorun kii mu enikeni ni tipa – tipa lati se ti Oun. Olorun je Alaanu nitori  Ijolododo Re, bi a ba se fi okan ope wa gba ebun ofe Igbala re si tabi de la o je ere ati Igbadun ebun oore ofe Re (Deut. 30:15 - 19)
5.      Gba Jesu Kristi sinu aye Re, bi aye ba buru, ko ye ki Orun ko tun buru fun O. loni lojo Igbala re. ola le pe ju fun o. (Acts. 16:31; Luku 19:8 - 10)  

AKOKO ADURA.   
1.      Oluwa gba ma se jeki nfi aye mi ba Orun mi je.
2.      Mase jeki n de Orun mo ottito
3.      Mase jeki ebun ofe naa bomo mi lowo tabi sii lo kuro laye mi.
4.      Awon ti ko tii mo, ki won o le mo O ni Oluwa ati Olorun won.
5.      Ninu ile Olorun wa maa joba n so.
6.      Ni Orile ede yii, maa gba okunkun laye lati bori imole Re Oluwa.

IKU NIPASE ADAMU ATI IYE NIPASE JESU KRISTI

Ifaara:             Ninu ipin bi ona maarun (5 sections by the outline), ti a lee pin Iwe Romu si, ipin Akoko se alaye nipa Ile Igbejo Kootu (The court of law and God’s wrath) Olorun ati ibinu Olorun. A n pari ipin akoko yii pelu eko yii nipa sise agbeyewo bi aye se ri ati ona abayo re.                 


I. Tani Adamu / Who was Adam?
            Ninu Bibeli, iru orisi Omo bii meta lo wa. Bibeli laa ye wa wipe :-
1.      Adamu, Omo ti a da (The created son) (Luku 3:38);
2.      Jesu Kristi Omo bibi kan soso (the only begotten son of God) (John 3:16; Luku 2:11); ati
3.      Omo eyin Kristi, awon ti a so dOmo(Christians are adopted children of God)(Roman 8:23;9:4; Galatia 3:26; Ephesians 1:5.)
Adamu je Omo Olorun ti a da. Lati ipase Adamu, opo nkan lo sele ti o pagidina Ibare, Ibarin ati alafia awa eniyan pelu Olorun (Romans 3:23; 5:1-2). Lara awon nkan ti o sele wonyii so eniyan di eniti o ru ibinu Olorun soke. Eniyan ba ara re ninu kootu Olorun(Genesisi 3:9 -19) ni alae ri tabi ri alagbejo ro (Advocate). Eniyan di eni irira, iyapa ati egbin si Olorun Eleda re. Eyi ni ipo ti eniyan ati aye wa si Olorun. Ko si te Olorun lorun. Lati igba naa wa, ni Olorun ti nwa ona lati mu eniyan pada sodo ara Re.
II. Tani Jesu Kristi / Who is Jesus Christ
            Jesu Kristi ni Olugbala Jesus (Christ is the Messiah); Omo Olorun (the son of God) – Matt. 1:16, 21; 16:16. The same yesterday, today and fo ever (okan naa lana, loni ati titi aye) Heb. 13:8; 1:3 
III. BIBELI KIKA (Romu 5.12-21).
Se afayo bi iku se wonu aye ati bi iye se wonu aye nipase Adamu ati Jesu kristi.
Adamu (Apere eniyan)                                               Jesu Kristi (Olugbaala eniyan)
            (vs12 – 14)                                                                  (Vs 15 -16)
Ese wonu aye nipase Adamu.                                        Ninu Jesu Kristi ebun oore ofe pupo wonu aye
Ofin ati iku nitori ese wonu aye                          Ninu Jesu Kristi idalare wonu aye.
V. 17 Nipase Adamu iku joba                                      Nipase Jesu Kristi iye ti konipekun joba.
V. 18 Nipase Adamu idajo idalebi                                Nipase Jesu Kristi idajo idalare.
V. 19 Nipase Adamu aegboran joba                             Nipase Jesu Kristi igboran ninu ododo di pupo.
V. 20 Nipase Adamu ofin n muni jabo               Nipase Jesu Kristi oore –ofe nifa ni losoke tabi di pupo
V. 21 Nipase Adamu ese n joba si iku                          Nipase Jesu Kristi, oore –ofe n joba sinu ife ati iye aenipekun Olorun.
Akiyesi.
1.      Itan Adamu ni a nka loni, Ise Igbala ti Jesu Kristi ti pari fun iran eniyan “ko ti, bee ni ko si sa’. Ise Igbala yii lo yo enikeni ti o ba gba Jesu Kristi gbo kuro ninu ogbun ibinu Olorun ti mba yorisi iku ati Orun apadi.
2.      Aeni Omo Olorun (Jesu Kristi) ko jeki eniyan ni IYE. Aeni iye le mu eniyan padanu iye aenipekun. Eyi le mu ki eniyan ku iku ti ara, ku iku ti emi, ki o si tun ku iku ayeraye (I John 5:6 -12)
3.      Niwon igbati Adamu ti kuro ninu aye anfani wa fun iwo ati emi lati fi igbagbo wa ro mo IYE ninu Jesu Kristi. Ki a gba a, ki a lo o (Romu 11:31 -32) ati ki a si duro sinsin ninu Re.
4.      Bi aye wa ko ba ti ri bi o se ye ki ori, eyi ko wipe aye titun ninu Jesu Kristi soro lati gbe. O ye ki a gbe igbe aye wa bii eniti Iye Jesu Kristi ngbe inu re. eyi yoo mu wa gbe igbe aye igboran si Olorun nipa bibori tabi yiya go fun ese; sisan idiyele tabi irubo ninu irin ajo Igbagbo yoo rorun fun wa lati se (Romu 8:12 -17) lati kede Ihinrere ninu oro ati ise wa yoo si leke ohun gbogbo. (Romu 1:16)
Akoko Adura.
1.       Mase jeki ise ati aye Adamu tun ma jeyo ninu aye mi. jowo ran mi lowo, mu mi bori eran ara.
2.       Mase jeki awon agbekale miran ti mo le se abapade ninu aye mu mi sina ijoba Re Oluwa.
3.       Oore – ofe ti n go fifi gbogbo ojo aye mi sin O, kede Ihinrere ati ribi desi ni ile ologo je ipin mi.
4.       Bi aye ba daru, ti ko si ni itumo, mase jeki n je eni ti yoo ma da aye ru. Gba mi lowo adaye eni ru.