Bibeli:
(Hosea 2: 14 – 23)
(Ese.14 - 15) – Se afayo Igbese ti Woli Hosea fe gbe bii ona lati se atunse pelu
Gomeri (Iyawo to sagbere
lo)
1. Kiyesi emi o tan – an, lati mu wa si aginju, pelu oro itunu
2. Emi yoo fun –un ni ogba ajara re lati ibe lo (Ohun didara).
3. Ki o le soro bi igba atijo (bi ojo ti o jade wa lati Egipti).
(Vs. 16 – 18) – Se afayo ireti Woli Hosea, ti n reti lati odo Gomeri ti o fe ba
se atunse.
1. Yoo si se ni ojo naa iwo (Gomeri) yoo pe mi ni oko mi.
2. Iwo ki yoo pe mi ni, Baali mo (oruko egan, yeye ati ikosile).
3. Awon eranko, eye ati ohun ti n rako lori ile yoo je apaere majemu (nitori ni
igbo ni won wa).
4. Ki yoo si Orun ida ogun mo ninu aye (alaafia yoo si joba).
(Ese. 19 – 23) – Se afayo ohun ti yoo je abajade atunse ti Woli Hosea yoo ba
Gomeri (Iyawo to sagbere
lo) se.
1. Emi o si fe o fun aara mi titi laelae ni ododo, ni idajo ni yonu ati
ni aanu.
2. Olorun yoo da awon Orun ati aye lohun (bi won ba ti n pe) – Ese. 21.
3. Ile yoo mu eso ti o dara jade (koni si iyan oun aeni mo) – Ese. 22.
4. Imupada bo sipo yoo sele (Emi o si wi fun awon ti kii se eniyan mi pe, Iwo
ni eniyan mi; oun naa yoo si wipe Iwo ni Olorun mi).
Akiyesi.
1. Ife ti Olorun fe wa, ko kerre. Ojojumo ni Olorun n wa ona lati fi han awa
eniyan pe oun fe wa. O ma n dun Olorun de okan re ti a ko ba ko ibi ara si ife
Re yii. (Gen. 6: 5 – 7)
2. Ogbon ati agbara eniyan ni ibiti o gbe de mo. (Ibase lodo Olorun, Eniti o da
wa ati lodo esu, olutanije wa). Sugbon ti a aba saba Olorun, Olorun yoo gba wa
pada esu yoo si sa kuro lodo wa. (Efesu 6: 11 -13; Jakobu 4: 7 – 8).
3. Eniti yoo segbe, koni se alaesegbe. Ife Olorun fun wa ko wipe eniti o yan
lati segbe ma segbe (Joh. 3:16 – 18).
4. Ife Olorun si wa, nigbati a ba se, a gba ijiya ese laye lati mu wa ronu
piwada. Nigbati a ba tun yipada si Odo Re, ife Olorun a tun mu Ibukun irorun,
isegun, ayo ati Alaafia pada fun wa wa. Eyi fi han pe ife Olorun si wa duro
titi laelae. (Romu 8:31 – 39)
Bibeli:
(Hosea 2: 6 -13)
(Ese.6– 7) – Se afayo Igbese idajo ti Olorun gbe ti Gomeri (Iyawo to sagbere
lo).
1. Kiyesi, emi o fi egun sagbara yii ona re ka.
2. Emi o si mo odi, ti oun ki yoo fi ri ona re mo.
3. Oun o si lepa awon ayanfe re, ki yoo le ba won.
4. Oun yoo si wa won, ki yoo ri won (awon to ba sagbere lo.).
5. Nigbana yoo wipe, Oun o pada to oko re isaaju lo
6. Nitori ti o san fun un, nigba naa ju ti isisiyi lo.
(Ese. 8 – 9) – Se afayo asiri igbese idajo Olorun ti O gbe ti Gomeri.
1. Oun ko i tii mo pe Olorun ni eniti o fun un ni oka, oti waini titun ati
Ororo.
2. Olorun ni eniti o mu fadaka ati wura re po sii, ti won fi se baali.
3. Olorun yoo pada mu oka re kuro ni akoko re ati oti waini ni igba re.
4. Olorun yoo gba irun aguntan ati ogbo Re pada ti O fi bo ihoho re.
(Ese. 10 – 13) – Se afayo abajade / ohun ti idajo Olorun yoo mu ba Gomeri.
1. Ni isisinyi ni emi o si itiju re sile loju awon ayanfe re, enikeni ki yoo si
gbaa.
2. Olorun yoo fi opin si gbogbo ayo re, ojo ase re, osu titun ati ojo isinmi
re, gbogbo owo re.
3. Olorun yoo pa ajara re ati igi opoto re run.
4. Olorun yoo so won di igbo awon eranko igbe yoo si je won.
5. Olorun yoo be oju baali wo lara re nibiti o gbe fi turari jona fun won.
6. Oruka eti, ohun oso re ti o fi to awon ayanfe re leyin ti o fi gbagbe Oluwa
– yoo dibaje.
Akiyesi.
1. Olorun fi ife Re alailegbe fe awon Omo Israeli bee gege ni O si fe awa naa
loni nitori ohun ni o wa
(Orin Dafidi 24:1; Johanu 3:16; Matt. 5:45).
2. Bi Olorun ti fe wa to yii, ohun ti o korira ni ese, okan ninu iwa ti o le mu
wa da ese kiakia ni aeni Iberu olorun lokan wa. Nipa bee kii pe ti a fi yago
kuro lodo Olorun, eniti o fe wa nipa aeni emi iberu wa.
3. Ohun gbogbo ti a ni lo fun igbaye gbadun wa ni Olorun ti da siwaju awa
eniyan. Sibesibe awon irorun
wonyii ni a n si lo, ti asilo yii si n mu wa jina si Olorun ti O le mu ki o
binu si wa.
4. Eko yii n laaye wa wipe, dipo ti a ba fi igbaye gbadun wa sin Olorun ki o le
tun bo ma po sii, n se ni a
fi n mu Olorun binu (Vs. 12 – 13), eyiti ko ye ki o ri bee.
Bibeli:
(Hosea 2: 1 – 5; I Korinti 10: 1 – 13)
(Ese.1 – 3 ) – Se afayo bi Olorun se pe awon Omo Gomeri si akiyesi iwa iya won–
Apere esun agbara - I.
1. E wi fun arakunrin yin Ammi (1: 8 - 9) ati fun arabirin yin Ruhama – (1:6)
2. E ba iya yin wijo nitori oun kii se aya mi, emi ki ise oko re.
3. Nitori naa ki o mu gbogbo agbere re kuro ati pansaga re kuro larin oyan re.
4. Ki emi maa ba tuu si ihoho bi ojo ti a bi i.
5. Emi o si gbe e kale bi ile gbigbe, wmi o si fi oungbe paa ku.
(Ese. 4 – 5) – Se afayo bi Olorun se pe awon Omo Gomeri si akiyesi iwa iya won –
Apere esun bi ese O
bi o se le di ti Omo - II.
1. Emi ki yoo si saanu fun awon Omo re, nwon je omo agbere.
2. Nitori ti iya won huwa pansaga obinrin.
3. Entiti o loyun won ti se ohun itiju (nipa pipada si aye agbere – nitori ti o
ran ti aadun ti n be nibe).
Akiyesi.
1. Olorun wa je Eniti n ma fi aye sile fun gbogbo eniyan lati ri ara won he
nigbati n won ba ye kuro loju ona fun ironupiwada. (Orin Dafidi 19: 11 – 13)
2. Igbese miran ti Olorun ma n gbe ni wipe, O maa fi ohun ti a ri se apere fun
wa ki eniyan ba le tete yipada ki o ma ba si awawi (Itan oninakuna kuna omo
- Luku 15: 17 – 21)
3. Lokan Olorun, ko fe ki a fi elomiran tabi nkan ropo Oun ninu okan ati aye
wa. Ifi ejo tabi esun kan Gomeri niwaju awon Omo re je apere fun wa loni.
(I Korinti 10: 1 – 13)
4. Yiya kuro lodo Olorun tabi kuro lona Re ma n je ohun ti o le pagidina siso
Ibukun eni di pupo ati anfani miran gbogbo. Ki eyi maa ba ri be ni eko yii se
se pataki fun wa lati koo (Heberu 4:1 – 2 )
Bibeli Kika:
(Hosea 1: 1 – 9)
(Ese. 1) – Se afayo, laye awon Oba bii melo ti Woli Hosea se ise irnase Woli re .
1. Oro Oluwa to Hosea wa ni awon ojo Ussiah, Jolamu, Ahasi, ati Hesekiah, awon
Oba Juda (Ijoba Isale)
2. Oro Oluwa to Hosea wa, ni awon Ojo Jeroboamu Omo Joasi Oba Israel (Ijoba
Oke)
(Ese. 2 – 9) – Se afayo, bi Olorun ti bere lati fi aworan awon Omo Israeli
han Woli Hosea.
1. Lo fe alagbere Obinrin kan fun ara re ati awon omo pansaga.
2. Nitori ile yii ti se agbere gidigidi kuro leyin Oluwa.
3. Hosea si fe Gomeri (ese.3.) Omobirin Diblaimu, o si bi omokunrin – Jesreeli
(ese. 4) Loruhama (ese 6), ati Loammi (Ese.9).
(Ese. 2 – 9) – Se afayo awon itumo ti Woli Hosea fun awon omo ti won bi
1. ese. 4 Jesreeli – nitori niwon igba die, Oluwa yoo be eje Jesreeli wo lara ile
Jehu lati fi opin si Ijoba ile Israeli
2. Ese. 6 Loruhama – nitori Oluwa ki yoo tun saanu fun ile Israeli mo nitori yoo
mu won kuro.
3. Ese. 9 Loammi – nitori eyin ki se eniyan mi emi kii se Olorun yin.
(Ese. 7) – Se afayo igbese ti Olorun fe gbe si Juda (Ijoba Isale) ni iyato si
Israeli (Ijoba oke)
1. Emi o saanu fun ile Juda.
2. Emi o si fi Oluwa Olorun won gba won la.
3. Emi ki yoo si fi ida, ogun, esin tabi elesin gba won la.
Akiyesi.
1. Gege bi agbekale Olorun, ko to, pe ki Alufa, Woli, Ajihinrere a.b.b.l lo fe
eniti o ko aya / oko re sile tabi ti o je alagbere (iba se Lokunrin / lobinrin)
(Lefitiku 11:43 – 45; 21:7; I Peteru 1:15 – 16).
2. Eko yii n so bi Israeli (Ijoba Oke) se je eniti ko se fokan tan
(unfaithfull) fun Olorun ati igbese ti Olorun le gbe bi o ba tun waye lode oni
(Deut 28: 47 – 48).
3. Sibe –sibe, nibiti awon miran ti n gba ijiya aeni iberu Olorun ninu aye won,
nibe ni awon elomiran yoo si ma ri aanu gba lowo Olorun yii kan na. (Romu 9:16;
18 – 24).