Sunday, August 25, 2013

HOSEA FE GOMERI



Bibeli Kika: (Hosea 1: 1 – 9)


(Ese. 1) – Se afayo, laye awon Oba bii melo ti Woli Hosea se ise irnase Woli re .
1. Oro Oluwa to Hosea wa ni awon ojo Ussiah, Jolamu, Ahasi, ati Hesekiah, awon Oba Juda (Ijoba Isale)
2. Oro Oluwa to Hosea wa, ni awon Ojo Jeroboamu Omo Joasi Oba Israel (Ijoba Oke)

(Ese. 2 – 9) – Se afayo, bi Olorun ti  bere lati fi aworan awon Omo Israeli han Woli Hosea.
1. Lo fe alagbere Obinrin kan fun ara re ati awon omo pansaga.
2. Nitori ile yii ti se agbere gidigidi kuro leyin Oluwa.
3. Hosea si fe Gomeri (ese.3.) Omobirin Diblaimu, o si bi omokunrin – Jesreeli (ese. 4) Loruhama (ese 6), ati Loammi (Ese.9).

(Ese. 2 – 9) – Se afayo awon itumo ti Woli Hosea fun awon omo ti won bi
1. ese. 4 Jesreeli – nitori niwon igba die, Oluwa yoo be eje Jesreeli wo lara ile Jehu lati fi opin si Ijoba ile Israeli
2. Ese. 6 Loruhama – nitori Oluwa ki yoo tun saanu fun ile Israeli mo nitori yoo mu won kuro.
3. Ese. 9 Loammi – nitori eyin ki se eniyan mi emi kii se Olorun yin.

(Ese. 7) – Se afayo igbese ti Olorun fe gbe si Juda (Ijoba Isale) ni iyato si Israeli (Ijoba oke)
1. Emi o saanu fun ile Juda.
2. Emi o si fi Oluwa Olorun won gba won la.
3. Emi ki yoo si fi ida, ogun, esin tabi elesin gba won la.

Akiyesi.
1. Gege bi agbekale Olorun, ko to, pe ki Alufa, Woli, Ajihinrere a.b.b.l lo fe eniti o ko aya / oko re sile tabi ti o je alagbere (iba se Lokunrin / lobinrin) (Lefitiku 11:43 – 45; 21:7; I Peteru 1:15 – 16).
2. Eko yii n so bi Israeli (Ijoba Oke) se je eniti ko se fokan tan (unfaithfull) fun Olorun ati igbese ti Olorun le gbe bi o ba tun waye lode oni (Deut 28: 47 – 48).
3. Sibe –sibe, nibiti awon miran ti n gba ijiya aeni iberu Olorun ninu aye won, nibe ni awon elomiran yoo si ma ri aanu gba lowo Olorun yii kan na. (Romu 9:16; 18 – 24).


No comments:

Post a Comment