Sunday, August 25, 2013

IDAJO GOMERI: APERE FUN WA


Bibeli: (Hosea 2: 6 -13)

(Ese.6– 7) – Se afayo Igbese idajo ti Olorun gbe ti Gomeri (Iyawo to sagbere lo).
1. Kiyesi, emi o fi egun sagbara yii ona re ka.
2. Emi o si mo odi, ti oun ki yoo fi ri ona re mo.
3. Oun o si lepa awon ayanfe re, ki yoo le ba won.
4. Oun yoo si wa won, ki yoo ri won (awon to ba sagbere lo.).
5. Nigbana yoo wipe, Oun o pada to oko re isaaju lo
6. Nitori ti o san fun un, nigba naa ju ti isisiyi lo.

(Ese. 8 – 9) – Se afayo asiri igbese idajo Olorun ti O gbe ti Gomeri.
1. Oun ko i tii mo pe Olorun ni eniti o fun un ni oka, oti waini titun ati Ororo.
2. Olorun ni eniti o mu fadaka ati wura re po sii, ti won fi se baali.
3. Olorun yoo pada mu oka re kuro ni akoko re ati oti waini ni igba re.
4. Olorun yoo gba irun aguntan ati ogbo Re pada ti O fi bo ihoho re.

(Ese. 10 – 13) – Se afayo abajade / ohun ti idajo Olorun yoo mu ba Gomeri.
1. Ni isisinyi ni emi o si itiju re sile loju awon ayanfe re, enikeni ki yoo si gbaa.
2. Olorun yoo fi opin si gbogbo ayo re, ojo ase re, osu titun ati ojo isinmi re, gbogbo owo re.
3. Olorun yoo pa ajara re ati igi opoto re run.
4. Olorun yoo so won di igbo awon eranko igbe yoo si je won.
5. Olorun yoo be oju baali wo lara re nibiti o gbe fi turari jona fun won.
6. Oruka eti, ohun oso re ti o fi to awon ayanfe re leyin ti o fi gbagbe Oluwa – yoo dibaje.

Akiyesi.
1. Olorun fi ife Re alailegbe fe awon Omo Israeli bee gege ni O si fe awa naa loni nitori ohun ni o wa
(Orin Dafidi 24:1; Johanu 3:16; Matt. 5:45).
2. Bi Olorun ti fe wa to yii, ohun ti o korira ni ese, okan ninu iwa ti o le mu wa da ese kiakia ni aeni Iberu olorun lokan wa. Nipa bee kii pe ti a fi yago kuro lodo Olorun, eniti o fe wa nipa aeni emi iberu wa.
3. Ohun gbogbo ti a ni lo fun igbaye gbadun wa ni Olorun ti da siwaju awa eniyan. Sibesibe awon irorun
wonyii ni a n si lo, ti asilo yii si n mu wa jina si Olorun ti O le mu ki o binu si wa.
4. Eko yii n laaye wa wipe, dipo ti a ba fi igbaye gbadun wa sin Olorun ki o le tun bo ma po sii, n se ni a
fi n mu Olorun binu (Vs. 12 – 13), eyiti ko ye ki o ri bee.

No comments:

Post a Comment