Sunday, August 25, 2013

OKUNRIN TI N WA ONA LATI SATUNSE PELU IYAWO RE ALAGBERE


Bibeli: (Hosea 2: 14 – 23)

(Ese.14 - 15) – Se afayo Igbese ti Woli Hosea fe gbe bii ona lati se atunse pelu Gomeri (Iyawo to sagbere
lo)
1. Kiyesi emi o tan – an, lati mu wa si aginju, pelu oro itunu
2. Emi yoo fun –un ni ogba ajara re lati ibe lo (Ohun didara).
3. Ki o le soro bi igba atijo (bi ojo ti o jade wa lati Egipti).
(Vs. 16 – 18) – Se afayo ireti Woli Hosea, ti n reti lati odo Gomeri ti o fe ba se atunse.
1. Yoo si se ni ojo naa iwo (Gomeri) yoo pe mi ni oko mi.
2. Iwo ki yoo pe mi ni, Baali mo (oruko egan, yeye ati ikosile).
3. Awon eranko, eye ati ohun ti n rako lori ile yoo je apaere majemu (nitori ni igbo ni won wa).
4. Ki yoo si Orun ida ogun mo ninu aye (alaafia yoo si joba).


(Ese. 19 – 23) – Se afayo ohun ti yoo je abajade atunse ti Woli Hosea yoo ba Gomeri (Iyawo to sagbere
lo) se.
1. Emi o si  fe o fun aara mi titi laelae ni ododo, ni idajo ni yonu ati ni aanu.
2. Olorun yoo da awon Orun ati aye lohun (bi won ba ti n pe) – Ese. 21.
3. Ile yoo mu eso ti o dara jade (koni si iyan oun aeni mo) – Ese. 22.
4. Imupada bo sipo yoo sele (Emi o si wi fun awon ti kii se eniyan mi pe, Iwo ni eniyan mi; oun naa yoo si wipe Iwo ni Olorun mi).

Akiyesi.

1. Ife ti Olorun fe wa, ko kerre. Ojojumo ni Olorun n wa ona lati fi han awa eniyan pe oun fe wa. O ma n dun Olorun de okan re ti a ko ba ko ibi ara si ife Re yii. (Gen. 6: 5 – 7)
2. Ogbon ati agbara eniyan ni ibiti o gbe de mo. (Ibase lodo Olorun, Eniti o da wa ati lodo esu, olutanije wa). Sugbon ti a aba saba Olorun, Olorun yoo gba wa pada esu yoo si sa kuro lodo wa. (Efesu 6: 11 -13; Jakobu 4: 7 – 8).
3. Eniti yoo segbe, koni se alaesegbe. Ife Olorun fun wa ko wipe eniti o yan lati segbe ma segbe (Joh. 3:16 – 18).
4. Ife Olorun si wa, nigbati a ba se, a gba ijiya ese laye lati mu wa ronu piwada. Nigbati a ba tun yipada si Odo Re, ife Olorun a tun mu Ibukun irorun, isegun, ayo ati Alaafia pada fun wa wa. Eyi fi han pe ife Olorun si wa duro titi laelae. (Romu 8:31 – 39)

No comments:

Post a Comment